Exodus 33:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA tún pe Mose, ó ní, “Dìde kúrò níhìn-ín, ìwọ ati àwọn eniyan tí o kó wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé n óo fún arọmọdọmọ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Dide, gòke lati ihin lọ, iwọ ati awọn enia na ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, si ilẹ ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi i fun:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Éjíbítì wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí èmi ti pinnu ní ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ.’