Exodus 33:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bá wí fún OLUWA pé, “Ṣebí ìwọ OLUWA ni o sọ pé kí n kó àwọn eniyan wọnyi wá, ṣugbọn o kò tíì fi ẹni tí o óo rán ṣìkejì mi hàn mí. Sibẹsibẹ, o wí pé, o mọ̀ mí o sì mọ orúkọ mi, ati pé mo ti rí ojurere rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun OLUWA pe, Wò o, iwọ wi fun mi pe, Mú awọn enia wọnyi gòke lọ: sibẹ̀ iwọ kò jẹ ki emi ki o mọ̀ ẹniti iwọ o rán pẹlu mi. Ṣugbọn iwọ wipe, Emi mọ̀ ọ li orukọ, iwọ si ri ore-ọfẹ li oju mi pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sọ fún OLÚWA pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́ nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojú rere mi pẹ̀lú.’