Exodus 33:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, bí inú rẹ bá dùn sí mi, fi ọ̀nà rẹ hàn mí, kí n lè mọ̀ ọ́, kí ǹ sì lè bá ojurere rẹ pàdé. Sì ranti pé àwọn eniyan rẹ ni àwọn eniyan wọnyi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, fi ọ̀na rẹ hàn mi nisisiyi, ki emi ki o le mọ̀ ọ, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ: ki o si rò pe orilẹ-ède yi enia rẹ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́, kí n sì le máa wá ojú rere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀ èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”