Exodus 33:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA dá Mose lóhùn pé, “N óo ṣe ohun tí o wí, nítorí pé inú mi dùn sí ọ, mo sì mọ orúkọ rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o ṣe ohun yi ti iwọ sọ pẹlu: nitoriti iwọ ri ore-ọfẹ li oju mi, emi si mọ̀ ọ li orukọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti bèrè, nítorí inú mi dún sí o, èmi sì mọ̀ ọ́ nípa orúkọ rẹ̀.”