Exodus 33:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose a máa pa àgọ́ àjọ sí òkèèrè, lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli, ó sì sọ ọ́ ní àgọ́ àjọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní ohunkohun láti bèèrè lọ́dọ̀ OLUWA yóo lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà, tí ó wà lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si mú agọ́ na, o si pa a lẹhin ibudó, li òkere rére si ibudó; o pè e ni Agọ́ ajọ. O si ṣe, olukuluku ẹniti mbère OLUWA o jade lọ si agọ́ ajọ, ti o wà lẹhin ibudó.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bèrè OLÚWA yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó.