Exodus 34:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA wí fún Mose pé, “Mo dá majẹmu kan, n óo ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú àwọn eniyan náà, irú èyí tí ẹnikẹ́ni kò rí rí ní gbogbo ayé tabi láàrin orílẹ̀-èdè kankan. Gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń gbé ààrin wọn yóo sì rí iṣẹ́ OLUWA, nítorí ohun tí n óo ṣe fún wọn yóo bani lẹ́rù jọjọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Kiyesi i, emi dá majẹmu kan: emi o ṣe ohun iyanu, niwaju gbogbo awọn enia rẹ irú eyiti a kò ti iṣe lori ilẹ gbogbo rí, ati ninu gbogbo orilẹ-ède: ati gbogbo enia ninu awọn ti iwọ wà, nwọn o ri iṣẹ OLUWA, nitori ohun ẹ̀ru li emi o fi ọ ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA wí pé: “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ èmi yóò se ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀ èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrin wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí èmi OLÚWA yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó