Exodus 34:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni dá majẹmu ninu gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà, kí ẹ má baà bá wọn dá majẹmu tán, kí ó wá di pé, nígbà tí wọn bá ń rúbọ sí oriṣa wọn, tí wọn sì ń ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn, wọn óo máa pè yín, pé kí ẹ máa lọ bá wọn jẹ ninu ẹbọ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nigbati nwọn ba nṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ti nwọn si nrubọ si oriṣa wọn, ti nwọn si pè ọ ti iwọ si lọ jẹ ninu ẹbọ wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Má a sọ́ra kí ẹ má se bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń se àgbérè tọ òrìsà wọn, tí wọ́n sì rúbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn.