Exodus 34:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ àìwúkàrà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ fún ọjọ́ meje ní àkókò àjọ náà, ninu oṣù Abibu, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún yín, nítorí pé ninu oṣù Abibu ni ẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ajọ aiwukàra ni ki iwọ ki o ma pamọ́. Ijọ́ meje ni iwọ o jẹ àkara alaiwu, bi mo ti paṣẹ fun ọ, ni ìgba oṣù Abibu: nitoripe li oṣù Abibu ni iwọ jade kuro ni Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú osù Ábíbù, nítorí ní osù náà ni ẹ jáde láti Éjíbítì wá.