Exodus 34:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ọ̀dọ́ aguntan ni kí ẹ máa fi ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí ó bá jẹ́ akọ pada, tí ẹ kò bá fẹ́ rà á pada, ẹ gbọdọ̀ lọ́ ọ lọ́rùn pa. Gbogbo àkọ́bí yín lọkunrin, ni ẹ gbọdọ̀ rà pada. “Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá siwaju mi ní ọwọ́ òfo láti sìn mí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada: bi iwọ kò ba si rà a pada, njẹ ki iwọ ki o ṣẹ́ ẹ li ọrùn. Gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọkunrin rẹ ni ki iwọ ki o rapada. Kò si sí ẹnikan ti yio farahàn niwaju mi lọwọ ofo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́ àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá ṣíwájú mi ní ọwọ́ òfo.