Exodus 34:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé n óo lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún yín, n óo sì fẹ ààlà yín sẹ́yìn. Kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo fẹ́ gba ilẹ̀ yín nígbà tí ẹ bá lọ sin OLUWA Ọlọrun yín, lẹẹmẹtẹẹta lọdọọdun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti emi o lé awọn orilẹ-ède nì jade niwaju rẹ, emi o si fẹ̀ ipinlẹ rẹ: bẹ̃li ẹnikẹni ki yio fẹ́ ilẹ̀-iní rẹ, nigbati iwọ o gòke lọ lati pejọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ẹrinmẹta li ọdún kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò lé orílẹ̀ èdè jáde níwájú rẹ, èmi yóò sì mú kí ìpín rẹ fẹ̀, ẹnikẹ́ni kì yóò gba ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá gòkè lọ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún kọ̀ọ̀kan láti farahàn níwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ.