Exodus 34:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose sì wà pẹlu OLUWA fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ó sì kọ ọ̀rọ̀ majẹmu náà, tíí ṣe òfin mẹ́wàá, sára àwọn wàláà òkúta náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wà nibẹ̀, lọdọ OLUWA li ogoji ọsán ati ogoji oru: on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi. On si kọwe ọ̀rọ majẹmu na, ofin mẹwa nì, sara walã wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè wà níbẹ̀ pẹ̀lú OLÚWA fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru (40) láì jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.