Exodus 34:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ pada ti orí òkè Sinai dé, pẹlu wàláà ẹ̀rí meji lọ́wọ́ rẹ̀, Mose kò mọ̀ pé ojú òun ń dán, ó sì ń kọ mànàmànà, nítorí pé ó bá Ọlọrun sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Mose sọkalẹ lati ori òke Sinai wá ti on ti walã ẹrí mejeji nì li ọwọ́ Mose, nigbati o sọkalẹ ti ori òke na wá, ti Mose kò mọ̀ pe awọ oju on ndán nitoriti o bá a sọ̀rọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Mósè sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Ṣínáì pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá OLÚWA sọ̀rọ̀.