Exodus 34:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o npa ãnu mọ́ fun ẹgbẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedede, ati irekọja, ati ẹ̀ṣẹ jì, ati nitõtọ ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijiyà; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn omọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1000), ó sì ń dárí jin àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń sọ̀tẹ̀ àti elẹ́sẹ̀. Ṣíbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ìkẹrin.”