Exodus 35:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ijọ́ mẹfa ni ki a fi ṣe iṣẹ, ṣugbọn ijọ́ keje ni yio ṣe ọjọ́ mimọ́ fun nyin, ọjọ́ isimi ọ̀wọ si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹ ninu rẹ̀ li a o lupa nitõtọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí OLÚWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa.