Exodus 35:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wá, olukuluku ẹniti ọkàn rẹ́ ru ninu rẹ̀, ati olukuluku ẹniti ọkàn rẹ̀ mu u fẹ́, nwọn si mú ọrẹ OLUWA wá fun iṣẹ agọ́ ajọ na, ati fun ìsin rẹ̀ gbogbo, ati fun aṣọ mimọ́ wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún OLÚWA, fún isẹ́ Àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún asọ mímọ́ náà.