Exodus 35:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún OLÚWA. Ẹnikẹ́ni tí ọ́ bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún OLÚWA ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ;