Exodus 36:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Kí Besaleli, ati Oholiabu ati olukuluku àwọn tí OLUWA fún ní ìmọ̀ ati òye, láti ṣe èyíkéyìí ninu iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ kíkọ́ ilé mímọ́ náà, ṣe é bí OLUWA ti pa á láṣẹ gan-an.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BESALELI ati Oholiabu yio si ṣiṣẹ, ati olukuluku ọlọgbọ́n inu, ninu ẹniti OLUWA fi ọgbọn ati oyé si, lati mọ̀ bi a ti ṣiṣẹ onirũru iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA ti palaṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bésálélì, Óhólíábù àti olúkúlùkù ọlọ́gbọ́n ẹni tí OLÚWA tí fún ní ọgbọ́n àti agbára láti mọ bí a ti í ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ ni kí wọn ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ.”