Exodus 36:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọ́n sì ṣe ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka tí wọ́n fi sí abẹ́ ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan fún àwọn ìkọ́ rẹ̀ mejeeji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà li o ṣe nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ rẹ̀ meji, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ rẹ̀ meji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì ṣe ogójì (40) fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn ìtẹ̀bọ̀ méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀.