Exodus 36:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn àkànpọ̀ igi náà wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn wọ́n so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi òrùka kinni, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn àkànpọ̀ igi kinni ati ekeji fún igun mejeeji àgọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si so wọn lù nisalẹ, a si so wọn lù pọ̀ li ori rẹ̀, si oruka kan: bẹ̃li o ṣe si awọn meji ni igun mejeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní igun méjèèjì yìí, pákó méjì ni ó wà níbẹ láti ìdí dé orí rẹ̀ wọ́n sì kó wọ́n sí òrùka kan; méjèèjì rí bákan náà.