Exodus 36:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Òpó marun-un ni wọ́n ṣe fún àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ṣe ìkọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n yọ́ wúrà bo àwọn òpó náà, ati àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi gbé àwọn aṣọ títa náà kọ́, ṣugbọn idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn maraarun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati opó rẹ̀ mararun ti on ti kọkọrọ wọn: o si fi wurà bò ọnà ori wọn, ati ọjá wọn: ṣugbọn idẹ ni ihò-ìtẹbọ wọn mararun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
wọ́n sì ṣe òpó márùn-ún pẹ̀lú ìkọ́ wọn. Wọ́n bo orí àwọn òpó náà àti ìgbànú wọn pẹ̀lú wúrà, wọn sì ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ márùn-ún wọn ní idẹ.