Exodus 38:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gígùn apá àríwá àgọ́ náà jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ pẹlu, ogún ni àwọn òpó rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn sì jẹ́ ogún pẹlu. Idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun ìha ariwa ọgọrun igbọnwọ, opó wọn jẹ́ ogún, ati ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta (46 meters) ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.