Exodus 38:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gígùn aṣọ títa fún apá ìwọ̀ oòrùn jẹ́ aadọta igbọnwọ, òpó rẹ̀ jẹ́ mẹ́wàá, àwọn àtẹ̀bọ̀ rẹ̀ náà jẹ́ mẹ́wàá; fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ, opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìhà ìwọ̀ oòrùn jẹ́ mítà mẹ́talélógún (23 meters) ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀.