Exodus 38:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó rẹ̀; ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, fadaka ni wọ́n yọ́ bo àwọn ìbòrí wọn, fadaka ni wọ́n sì fi bo gbogbo àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ihò-ìtẹbọ fun opó wọnni jẹ́ idẹ; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà; ati ibori ori wọn jẹ́ fadakà; ati gbogbo opó agbalá na li a fi fadakà gbà li ọjá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni. Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà; gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà.