Exodus 38:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n fi abẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró, ati aṣọ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ó gùn ní ogún igbọnwọ, ó sì ga ní igbọnwọ marun-un gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣọ títa ti àgbàlá náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na jẹ́ iṣẹ abẹ́rẹ, aṣọ-alaró, ati elesè-aluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ: ogún igbọnwọ si ni gigùn rẹ̀, ati giga ni ibò rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun, o bá aṣọ-tita agbalá wọnni ṣedede.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Aṣọ tita fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára iṣẹ́ alábẹ́rẹ́ ni. Ó jẹ́ mítà mẹ́sàn-án ní gígùn (9 meters), gẹ́gẹ́ bí aṣọ títa àgbàlá náà, àti gíga rẹ̀ jẹ mítà méjì (2. 3 meters),