Exodus 38:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Òpó mẹrin ni aṣọ títa tí ẹnu ọ̀nà yìí ní, pẹlu ìtẹ́lẹ̀ idẹ mẹrin. Fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, fadaka ni wọ́n sì fi bo àwọn ìbòrí òpó náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Opó wọn si jẹ́ mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ, mẹrin; kọkọrọ wọn jẹ́ fadakà, ati ibori ori wọn ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà.