Exodus 38:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ náà jẹ́ ìwọ̀n talẹnti mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹrin ìwọ̀n ṣekeli ó lé ọgbọ̀n (730), ìwọ̀n tí wọn ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo wurà ti a lò si iṣẹ na, ni onirũru iṣẹ ibi mimọ́ nì, ani wurà ọrẹ nì, o jẹ́ talenti mọkandilọgbọ̀n, ati ẹgbẹrin ṣekeli o din ãdọrin, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ńtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) àti ẹgbẹ̀rin (730) sékélì gẹ́gẹ́ bí i sékélì ibi mímọ́.