Exodus 38:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Fadaka tí àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn eniyan náà dájọ jẹ́ ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti, ati ẹẹdẹgbẹsan ìwọ̀n ṣekeli ó lé marundinlọgọrin (1,775), ìwọ̀n tí wọ́n máa ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n dá wúrà ati fadaka ati idẹ yìí jọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fadakà awọn ẹniti a kà ninu ijọ-enia jẹ́ ọgọrun talenti, ati ṣekeli ojidilẹgbẹsan o le mẹdogun, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sílífà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) talẹ́ntì àti òjìlélẹ́gbẹ̀sán ó lé mẹ́ẹ̀dógún sékélì (1,775) gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́