Exodus 38:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Olukuluku àwọn tí wọ́n tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n kà dá ìdajì ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan tí òfin wí, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ilé OLUWA ni wọ́n sì fi wọ̀n ọ́n, iye àwọn eniyan tí wọ́n kà jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ati ẹgbẹtadinlogun ó lé aadọjọ (603,550).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abọ ṣekeli kan li ori ọkunrin kọkan, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́, lori ori olukuluku ti o kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ le ẹgbẹtadilogun o le ãdọjọ enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ìwọ̀n gíráàmù márùn-ún ààbọ̀ (5. 5 grams) lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀tadínlógún-ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin (603,550 men).