Exodus 38:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọgọrun-un talẹnti fadaka yìí ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó ilé OLUWA ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn aṣọ títa. Ọgọrun-un talẹnti ni wọ́n lò láti ṣe ọgọrun-un ìtẹ́lẹ̀, talẹnti kọ̀ọ̀kan fún ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu ọgọrun talenti fadakà na li a ti dà ihò-ìtẹbọ wọnni ti ibi mimọ́, ati ihò-ìtẹbọ ti aṣọ-ikele na, ọgọrun ihò-ìtẹbọ ninu ọgọrun talenti na, talenti ka fun ihò-ìtẹbọ kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọgọ́run-ún talẹ́ntì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùnún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún talẹ́ntì náà talẹ́ntì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.