Exodus 39:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oríṣìí òkúta mejila ni ó wà níbẹ̀; orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dúró fún orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, wọ́n dàbí èdìdì, wọn sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila sí wọn lára, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Okuta wọnni si jasi gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn, bi ifin èdidi-àmi, olukuluku ti on ti orukọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ya mejejila.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá ọkan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnikọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.