Exodus 39:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi oruka rẹ̀ dè igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi pẹlu ọjá-àwọn aṣọ-aláró, ki o le ma wà lori onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ati ki igbàiya ni ki o máṣe tú kuro lara ẹ̀wu-efodi na; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn ṣo àwọn òrùka igbáàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù èfòdì ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí igbáàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù èfòdì náà gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.