Exodus 39:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tò wọ́n yípo etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà, fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣaworo kan ati pomegranate kan, ṣaworo kan ati pomegranate kan, yi iṣẹti aṣọ-igunwa na ká lati ma fi ṣiṣẹ alufa; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Aago àti pomégíránátè kọjú sí àyíká ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.