Exodus 39:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó fi òòlù lu wúrà, ó sì gé e tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn, wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ aláwọ̀ aró ati ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si lù wurà nì di ewé fẹlẹfẹlẹ, nwọn si là a li okùn wẹ́wẹ, ati lati fi ṣe iṣẹ ọlọnà sinu aṣọ-alaró, ati sinu elesè-àluko, ati sinu ododó, ati sinu ọ̀gbọ didara nì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára ni ti iṣẹ́ ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.