Exodus 39:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n tọ́jú àwọn òkúta onikisi, wọ́n jó wọn mọ́ ojú ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn, bí wọ́n ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si ṣiṣẹ́ okuta oniki ti a tò sinu oju-ìde wurà, ti a fin bi ifin èdidi-àmi ti a fin orukọ awọn ọmọ Israeli si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ṣìṣe òkúta óníkísì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.