Exodus 4:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Mose wí fún OLUWA pé, “OLUWA mi, n kò lè sọ̀rọ̀ dáradára kí o tó bá mi sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni lẹ́yìn tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ tán, nítorí pé akólòlò ni mí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì sọ fún OLÚWA pé, “Èmi jẹ́ akọ́lòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́ tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”