Exodus 4:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Inú bí OLUWA sí Mose, ó ní, “Ṣebí Aaroni, ọmọ Lefi, arakunrin rẹ wà níbẹ̀? Mo mọ̀ pé òun lè sọ̀rọ̀ dáradára; ó ń bọ̀ wá pàdé rẹ, nígbà tí ó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóo dùn gidigidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Inu OLUWA si ru si Mose, o si wipe, Aaroni arakunrin rẹ ọmọ Lefi kò ha wà? Emi mọ̀ pe o le sọ̀rọ jọjọ. Ati pẹlu, kiyesi i, o si mbọ̀wá ipade rẹ: nigbati o ba si ri ọ, on o yọ̀ ninu ọkàn rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbínú Ọlọ́run ru sókè sí Mósè, ó sì sọ pé, “Árónì ará Léfì arákùnrin rẹ ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ já gaara, ó ti wà ní ọ̀nà rẹ̀ báyìí láti pàdé e rẹ. Inú rẹ̀ yóò sì dùn ti ó bá rí ọ.