Exodus 4:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose pada lọ sí ọ̀dọ̀ Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan mi ní Ijipti, kí n lọ wò ó bóyá wọ́n wà láàyè.” Jẹtiro dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ ní alaafia.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si lọ, o si pada tọ̀ Jetro ana rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nlọ ki emi si pada tọ̀ awọn arakunrin mi ti o wà ni Egipti, ki emi ki o si wò bi nwọn wà li ãye sibẹ̀. Jetro si wi fun Mose pe, Mã lọ li alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè padà sí ọdọ Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Íjíbítí láti wò bóyá wọ́n sì wà láàyè ṣíbẹ̀.” Jẹ́tirò sì dáhùn, ó wí pé, “Má a lọ ni àlàáfíà.”