Exodus 4:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose bá gbé iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tòun ti ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si mú aya rẹ̀ ati awọn ọmọ-ọkunrin rẹ̀, o si gbé wọn gùn kẹtẹkẹtẹ kan, o si pada si ilẹ Egipti: Mose si mú ọpá Ọlọrun na li ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Éjíbítì. Ó sì mú ọ̀pa Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.