Exodus 4:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ fún Mose pé, “Nígbà tí o bá pada dé Ijipti, o gbọdọ̀ ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe níwájú Farao, ṣugbọn n ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kò sì ní jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Nigbati iwọ ba dé Egipti, kiyesi i ki iwọ ki o ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu, ti mo filé ọ lọwọ, niwaju Farao, ṣugbọn emi o mu àiya rẹ̀ le, ti ki yio fi jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì sọ fún Mósè pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Éjíbítì rí i pé ìwọ se iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Fáráò. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì ṣé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ.