Exodus 4:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọn kò bá gba àwọn àmì mejeeji wọnyi gbọ́, tí wọ́n sì kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, lọ bu omi díẹ̀ ninu odò Naili kí o sì dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀; omi náà yóo di ẹ̀jẹ̀ bí o bá ti dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, bi nwọn kò ba si gbà àmi mejeji yi gbọ́ pẹlu, ti nwọn kò si fetisi ohùn rẹ, njẹ ki iwọ ki o bù ninu omi odò nì, ki o si dà a si iyangbẹ ilẹ: omi na ti iwọ bù ninu odò yio di ẹ̀jẹ ni iyangbẹ ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba àwọn méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Náílì kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.”