Exodus 40:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, ìkùukùu OLUWA wà lórí àgọ́ náà lọ́sàn-án, iná sì máa ń jó ninu rẹ̀ lóru ní ìṣojú gbogbo àwọn eniyan Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti awọsanma OLUWA wà lori agọ́ na li ọsán, iná si wà ninu awọsanma na li oru, li oju gbogbo ile Israeli, ni gbogbo ìrin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwọ̀ọsánmọ̀ OLÚWA wà lórí Àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọ̀ọsánmọ̀ ní òru, ní ojú gbogbo ilé Ísírẹ́lì ní gbogbo ìrìnàjò wọn.