Exodus 40:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, gbé tabili náà wọ inú rẹ̀, pẹlu àwọn nǹkan tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, kí o sì tò wọ́n sí ààyè wọn. Lẹ́yìn náà, gbé ọ̀pá fìtílà náà wọ inú rẹ̀, kí o sì to àwọn fìtílà orí rẹ̀ sí ààyè wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si gbé tabili wọle, ki o si tò ohun wọnni ti o ni itò si ori rẹ̀; iwọ o si mú ọpá-fitila wọle, iwọ o si tò fitila rẹ̀ wọnni lori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì tò àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀.