Exodus 40:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Lẹ́yìn náà, mú òróró ìyàsímímọ́, kí o ta á sí ara àgọ́ náà, ati sí ara ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, kí o yà á sí mímọ́ pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, wọn yóo sì di mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si mù oróro itasori nì, iwọ o si ta a sara agọ́ na, ati sara ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀: yio si jẹ́ mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára Àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀sọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́.