Exodus 5:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Mose ati Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sọ fún un pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ pé, ‘Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, kí wọ́n lè lọ ṣe àjọ̀dún kan fún mi ninu aṣálẹ̀.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LẸHIN eyinì ni Mose ati Aaroni wọle, nwọn si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣe ajọ fun mi ni ijù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ”