Exodus 5:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao bẹ̀rẹ̀ sí na àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Wọn á máa bi wọ́n pé “Kí ló dé tí bíríkì tí ẹ mọ lónìí kò fi tó iye tí ó yẹ kí ẹ mọ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn olori awọn ọmọ Israeli, ti awọn akoniṣiṣẹ Farao yàn lé wọn, li a nlù, ti a si mbilère pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò ṣe iṣẹ nyin pé ni briki ṣiṣe li ana ati li oni, bi ìgba atẹhinwá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ yàn lára ọmọ Ísírẹ́lì ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?”