Exodus 5:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni kò fún wa ní koríko, sibẹ wọ́n ní dandan, a gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí à ń mọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń lù wá, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ará Ijipti gan-an ni wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A kò fi koriko fun awọn iranṣẹ rẹ, nwọn si nwi fun wa pe, Ẹ ṣe briki: si kiyesi i, a nlù awọn iranṣẹ rẹ; ṣugbọn lọwọ awọn enia rẹ li ẹbi wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, ṣíbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”