Exodus 5:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn wà ninu ewu, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé iye bíríkì tí àwọn ń mọ lojumọ kò gbọdọ̀ dín rárá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn olori awọn ọmọ Israeli si ri pe, ọ̀ran wọn kò li oju, lẹhin igbati a wipe, Ẹ ki o dinkù ninu iye briki nyin ojojumọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.”