Exodus 5:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ọlọrun ni yóo dájọ́ fún yín, ẹ̀yin tí ẹ sọ wá di ẹni ìríra níwájú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ẹ sì ti yọ idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi pa wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o wò nyin, ki o si ṣe idajọ; nitoriti ẹnyin mu wa di okú-õrùn li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀, lati fi idá lé wọn lọwọ lati pa wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn sì wí pé, “Kí OLÚWA kí ó wò yín, kí ó sì ṣe ìdájọ́! Ẹ̀yin ti mú wa dàbí òórùn búburú fún Fáráò àti àwọn òsìṣẹ̀ rẹ̀, ẹ sì ti fún wọn ni ìdà láti fi pa wá.”