Exodus 5:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọlọrun àwọn Heberu ni ó farahàn wá; jọ̀wọ́, fún wa ní ààyè láti lọ sí aṣálẹ̀ ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó má baà fi àjàkálẹ̀ àrùn tabi ogun bá wa jà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wipe, Ọlọrun awọn Heberu li o pade wa: awa bẹ̀ ọ, jẹ ki a lọ ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa; ki o má ba fi ajakalẹ-àrun tabi idà kọlù wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Hébérù tí pàdé wa. Ní ìsinsìnyìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ihà láti rú ẹbọ sí OLÚWA Ọlọ́run wa, kí ó má ba á fi àjàkálẹ̀-àrùn tàbí idà bá wa jà.”