Exodus 6:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “O óo rí ohun tí n óo ṣe sí ọba Farao; ó fẹ́, ó kọ̀, yóo jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, fúnra rẹ̀ ni yóo sì fi ipá tì wọ́n jáde.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Nigbayi ni iwọ o ri ohun ti emi o ṣe si Farao: nitori ọwọ́ agbara li on o ṣe jọwọ wọn lọwọ lọ, ati pẹlu ọwọ́ agbara li on o fi tì wọn jade kuro ni ilẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ní OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Fáráò pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.”